Nothing Special   »   [go: up one dir, main page]

Jump to content

Bayo Ojo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Christoper Adebayo Ojo
Federal Minister of Justice
In office
June 2005 – May 2007
AsíwájúAkin Olujinmi
Arọ́pòMichael Aondoakaa
Àwọn àlàyé onítòhún
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople's Democratic Party (Nigeria)
(Àwọn) olólùfẹ́Folashade
ProfessionLawyer

Christopher Adebayo Ojo, SAN fìgbà kan jẹ́ Attorney General ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó sì tún fìgbà kan jẹ́ olórí Nigerian Federal Ministry of Justice. Ó jẹ́ amòfin, ó sì láṣẹ láti ṣiṣẹ́ ní Nigeria, England àti Wales. Ó tún jẹ́ Senior Advocate of Nigeria.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ojo wá láti Ife-Ijumu, Kogi State,[3] ní Nigeria. Ó kẹ́kọ̀ọ́ alákòóbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Maiduguri àti Kaduna àti àwọn ẹ̀kọ́ ìyókù ní Zaria àti Kaduna State. Ó ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀ ní Ilorin, Kwara State, kí ó tó lọ sí University of Lagos (in Lagos) níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ òfin ní June 1977. Ó fẹ́ He is Hon. Justice Folashade Bayo-Ojo, wọ́n sì jọ ní ọmọ méjì, Babatomiwa àti Olubusola. Ó ní àbúrò ọkùnrin méjì, Daniel Oluwasegun Ojo àti Victor Olanrewaju Ojo.

Ojo di agbẹjọ́rò ní July 1978. Ó ní ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìfipábálòpọ̀ kan, níwájú Hon. Justice Anthony Iguh ti High Court of Justice, Enugu, ní ọdún 1978. Lásìkò náà, ó jẹ́ agùnbánirọ̀

Ó ṣiṣẹ́ ní Ministry of Justice, ní ìpínlẹ̀ Kwara, gẹ́gẹ́ bíi agbẹjọ́rò fún ìpínlẹ̀ náà fún ọdún mẹ́rin. Lásìkò yìí, ó gba ìwé-ẹ̀rí ní Royal Institute of Public Administration, ní London ní September, 1981. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí London School of Economics and Political Science, University of London, láti gboyè LLM ní September 1982. Ní March 1983, ó fi iṣẹ́ ìjọba sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ Oniyangi & Co gẹ́gẹ́ bíi olórí ilé-iṣẹ́ náà. Ní ọdún 1986, ó ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ tó pè ní Bayo Ojo & Co.

Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi Nigeria Bar Association (NBA) ní ọdún 2004. Nígbà kan náà ni wọ́n yàn án sípò Attorney General àti Minister of Justice[4] láti ọwọ́ President Olusegun Obasanjo.

Ní ọdún 2007, ó di ọmọ-ẹgbẹ́ United Nations International Law Commission. Títí di òní, ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Nasir EL-Rufai àti Nuhu Ribadu.

Àtòjọ àwọn iṣẹ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Mehler, Andreas; Melber, Henning; Walraven, Klaas Van (January 2007). Africa yearbook. BRILL. pp. 158–. ISBN 978-90-04-16263-1. https://books.google.com/books?id=VEqZ8rep_A0C&pg=PA158. Retrieved 9 May 2011. 
  2. Ojakaminor, Efeturi (2007). Aso Rock and the arrogance of power. Ambassador Publications. p. 272. https://books.google.com/books?id=srIuAQAAIAAJ. Retrieved 9 May 2011. 
  3. "Group backs Bayo Ojo for minister". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-09-30. Retrieved 2022-03-03. 
  4. Tucker, Andrew (2009-01-02). Queer visibilities: space, identity and interaction in Cape Town. Wiley-Blackwell. pp. 206–. ISBN 978-1-4051-8302-4. https://books.google.com/books?id=XQZJ1zGK8-oC&pg=PA206. Retrieved 9 May 2011. 
  5. https://www.pressreader.com/nigeria/thisday/20190326/281895889590691. Retrieved 2020-01-10 – via PressReader.  Missing or empty |title= (help)